Journal statistics
How to use the archive
When the cursor changes from an arrow to a pointing finger, it indicates a link that you may click on to select that item.
The blue buttons at the top can be selected to return to the overview or to run a search for specific information.
Most volumes have been split into two parts, each with separate articles. When you select a specific number, all of the articles will be listed with details of the author, date of publication, language and the size of the file that will be downloaded if you choose that option. Just click on the yellow "Download" button to transfer a copy of the article to your own computer or device.
- Language Family: Atlantic
- Topic #1: Sociolinguistics
Àṣamọ̀
Nínú iṣẹ́ ìwadǐ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa èdè àti ọ̀rọ̀ akọ-sábo, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ṣe àwárí rẹ̀ pé àwọn obìnrin máa ń lo àwọn ìsọwọ́sọ̀rọ̀ kan ju àwọn ọkùnrin lọ. Irúfẹ́ àwọn ìsọwọ́sọ̀rọ̀ yí ni àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ bíi Lakoff (1973) pè ni “èdè àwọn obìnrin”. Nínú ìwadǐ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ yí, mo ṣe ìwadǐ ìsọwọ́lò àwọn ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ ajẹmọ-ọ̀wọ̀ nínú eré àgbéléwò Ẹfúnsetán Aniwura (Ogunsola, Kelani, àti Íṣọ̀lá, 2005). Mo fi hàn pé àwọn obìnrin ń lo àwọn ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ ajẹmọ́-ọ̀wọ̀ ju àwọn okùnrin lọ. Sùgbọ́n, mo tẹ̀lé O’Bar àti Atkins (1980) àti Wetzel (1988) láti ṣe atótónu pé lílo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ ajẹmọ́-ọ̀wọ̀ jẹ́ àbùdá “èdè ọ̀lẹ” àti pé kìí ṣe àbùdá “èdè obìnrin”. Mo dábǎ pé ohun tí ó yẹ kí á maá fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ “èdè obìnrin” perí ni ìsọwọ́lò èdè tí ó jẹ́ pé àwọn obìnrin nìkan ni ìwadǐ ti fi hàn pé wọ́n ń lòó. Mo dábǎ pé ó yé kí ìyàtọ̀ ó wà láàrin “èdè ọ̀lẹ” tó jẹ́ pé àwọn obìnrin ni wọn ń lòó jù àti “èdè obìnri” tí àwùjọ sọ di ọ̀lẹ. Èyí fún wa ní àǹfààní láti bèèrè àwọn ìbéèrè ìpìlẹ̀ tó níí se pẹ̀lú àjọṣepọ̀ láàrin agbára, èdè, àti ọrọ akọ-sábo àti ìbáṣepọ̀ láàrin ìgbèrúyípadà èdè àti ìṣèyàtọ̀ alákọ-sábo.