Journal statistics
How to use the archive
When the cursor changes from an arrow to a pointing finger, it indicates a link that you may click on to select that item.
The blue buttons at the top can be selected to return to the overview or to run a search for specific information.
Most volumes have been split into two parts, each with separate articles. When you select a specific number, all of the articles will be listed with details of the author, date of publication, language and the size of the file that will be downloaded if you choose that option. Just click on the yellow "Download" button to transfer a copy of the article to your own computer or device.
- Language Family: Other Benue-Congo
- Topic #1: Phonology
Àṣamọ̀
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ ìwádìí tìṣáájú lórí ìgbésẹ̀ ìfàfòmọ́kún-ọ̀rọ̀ nínú èdè Yorùbá dá lórí ìpín-sí-ìsọ̀rí àwọn àfòmọ́ inú èdè yìí ní ìlànà mọfọ́lọ́jì, mọfo-síńtáàsì àti sẹ̀máńtíìkì. Títí di àkókò yìí, kò tíì sí akitiyan tí ó yẹ lórí ìtúpalẹ̀ ìbófinmu ajẹmọ́-mọfo-pròsódíìkì tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ tí a ṣẹ̀dá nípa ìgbésẹ̀ ìfàfòmọ́kún-ọ̀rọ̀, pàápàá jùlọ ìtúpalẹ̀ tó dá lórí tíọ́rì ajẹmótèé. Nítorí náà, oun tí iṣẹ́ ìwádìí yìí dá lé lórí ni ṣíṣe ìtúpalẹ̀ ìjìnlẹ̀ bí irúfẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe bá òfin ajẹmọ́-mọfo-pròsódíìkì mu. Tíọ́rì ajẹmọ́-etí-ìhun – Generalized Alignment (McCarthy & Prince, 1993), èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dà tíọ́rì ọptimálítì – ni ìtúpalẹ̀ náà gùnlé. Níwọ̀n ìgbà tó ti jẹ́ pé iṣẹ́ ìwádìí yìí dá lórí ṣíṣe àtúnyẹ̀wò ìgbésẹ̀ ìfàfòmọ́kún-ọ̀rọ̀ nínú èdè Yorùbá, púpọ̀ nínú àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò tí ó jẹyọ nínú pépà yìí wá láti inú àwọn iṣẹ́ ìwádìí tí a ti ṣe ṣáájú. Ṣùgbọ́n, oníṣẹ́-ìwádìí túbọ̀ bẹ àwọn aṣafọ̀ abínibí èdè Yorùbá méjì lọ́wẹ̀ láti rí i pé àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò náà bẹ́gbẹ́ mu, pàápàá jùlọ ìhun ìtumọ̀ wọn. Iṣẹ́ ìwádìí yìí fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ìgbésẹ̀ ìfàfòmọ́kún-ọ̀rọ̀ nínú èdè Yorùbá máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá nípa ìgbésẹ̀ yìí di ọ̀rọ̀ onísílébù méjì pàápàá jùlọ tí ó bá jẹ́ pé ìhun ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kò tó sílébù méjì. Ní pàtàkì jùlọ, pépà yìí ṣàwárí pé, nínú èdè Yorùbá, ìlànà ìgbésẹ̀ ìfàfòmọ́kún-ọ̀rọ̀ níí ṣe pẹ̀lú síso àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ tàbí àfòmọ́-àárín mọ́ etí apá òsì mọ́fíìmù ìpìlẹ̀ láti rí i pé etí apá ọ̀tún mọ́fíìmù ìpìlẹ̀ àti ti ọ̀rọ̀ onísílébù méjì tí a ṣẹ̀dá jọra wọn tàbí bára wọn mu. Nítorí náà, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìwádìí tìṣáájú, iṣẹ́ ìwádìí yìí fihàn gbangba-gbàǹgbà wí pé gbogbo àwọn ìlànà ìgbésẹ̀ ìfàfòmọ́kún-ọ̀rọ̀ nínú èdè Yorùbá ló jẹmọ́ síso àfòmọ́ mọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀; èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé òté ALIGN-RIGHT ga ju òté ALIGN-LEFT lọ nínú mọfọ́lọ́jì èdè Yorùbá. Lákòótán, pépà yìí tẹnumọ́ ọ wí pé ìdí tí Yorùbá fi jẹ́ èdè aláfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ ò ṣẹ̀yìn wí pé ìjọra tàbí ìbáramu ajẹmọ́-àyè gbọ́dọ̀ níí ṣe pẹ̀lú etí apá ọ̀tún ìhun nìkan.