Journal statistics
How to use the archive
When the cursor changes from an arrow to a pointing finger, it indicates a link that you may click on to select that item.
The blue buttons at the top can be selected to return to the overview or to run a search for specific information.
Most volumes have been split into two parts, each with separate articles. When you select a specific number, all of the articles will be listed with details of the author, date of publication, language and the size of the file that will be downloaded if you choose that option. Just click on the yellow "Download" button to transfer a copy of the article to your own computer or device.
- Language Family: Other Benue-Congo
- Topic #1: Classification
Àṣamọ̀
A ṣe àfiwe Ọ̀kọ̀ pẹ̀lú àwọn ìsọ̀rí èdè Benue Congo (BC) tó súnmọ́ ọn nípá lílo ọgbọ́n ìwádìí ìṣàfiwé ìdáọ̀rọ̀. Ìdá mẹtàdínlọ́gbọ̀n (27%) ni ìjọra tó wà láàárín wọn. Ìyàtọ̀ ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ láàárin ìsọ̀rí edè fojúhàn báyìí: Yorúboid àti Ebiroid (Ò̩kó̩/Yoruboid- ìdá mejìlélọ́gbọ̀n (32%), ìdá ogún 20%; Ọ̀kọ̀/Ebiroid- ìdá o̩gbò̩n, ìdá mé̩rìndínló̩gbò̩n. Ìyàtọ̀ pàtàkì ló fojú hàn láàrin Ọ̀kọ̀ àti Akpes àti àpapọ̀ Ukaan (Ikaan, Ishe, Auga, &Ayanran èyí tí a túnmọ̀ sí (AIKA)), tí Ọ̀kọ̀ ní ìjọra ọ̀rọ̀ ìdá méjìdínlógún pẹ̀lú Akpes, ìdá mẹ́tàdínlógún pẹ̀lú Ukaan, èyí tó yàtọ̀ sí ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tó ni pẹ̀lú ìsọ̀rí WBC. Ìwádìí fi hàn pé Ọ̀kọ̀ súnmọ́ Ebiroid àtí Yoruboid, ó sì takété sí Edoid, Nupoid, Akpes and Ukaan. Ìjọra ọ̀rọ̀ Ọ̀kọ̀ pẹ̀lú Yoruboid àti Ebiroid tó jú ti ìsọ̀rí àwọn èdè agbègbè rẹ̀ lọ (Edoid and Nupoid), àti ìyàtọ̀ díẹ̀ tó wà ní ìsúnmọ́ra látiYoruboid sí Ebiroid gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ sẹ ṣàfihàn rẹ lórí àwòrán atọ́ka-igi ń ṣàpẹrẹ pé ìdàpọ̀ kan wà ní agbègbè yìí. Ohun àrídìmú ni pé Ọ̀kọ̀ le máṣe é pín mọ́ ìsọ̀rí WBC yòókù, tó ní ìjọrà-ọ̀rọ̀ ìdá mẹ́rìnlélógún sí ìdá mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, pàápàá gẹ́gẹ́ bí ìjọra-ọ̀rọ̀ Ọ̀kọ̀ pẹ̀lú WBC ṣe wà láàrín ìdá mẹ́tàdínlógún sí ìdá mẹ́tàlélọ́gbọ́n. A dábàá ìgóríta agbedeméjì láti fààyè gba ìjọra yìí. Àgbéyẹ̀wò Ọ̀kọ̀ fihàn pé ó ní ẹka èdè méjì péré(Ọ̀kọ̀ àti Osayen). Ọ̀kọ̀/Eni ní ìjọra-ọ̀rọ̀ tó tó ìdá ọ̀gọ́rùn-ún (100%). Ọ̀kọ̀/ Osayen ní ìdá méjìdínláàádọ́rùn-ún (88%) ìjọra ọ̀rọ̀. Ìfarakínra èdè agbègbè kó ipa pàtàkì nínú pínpín Ọ̀kọ̀ láàárin BC.