Journal statistics

The archive of journals contains 739 items in 148 categories. To date, these have been downloaded 790,851 times.

How to use the archive

When the cursor changes from an arrow to a pointing finger, it indicates a link that you may click on to select that item.

The blue buttons at the top can be selected to return to the overview or to run a search for specific information.

Most volumes have been split into two parts, each with separate articles. When you select a specific number, all of the articles will be listed with details of the author, date of publication, language and the size of the file that will be downloaded if you choose that option. Just click on the yellow "Download" button to transfer a copy of the article to your own computer or device.

Download details
  • Language Family: Other Benue-Congo
  • Topic #1: Vowels
  • Topic #2: Phonology
Vowel Doubling in the Adaptation of English Loanwords in Yoruba Revisi Vowel Doubling in the Adaptation of English Loanwords in Yoruba Revisited

Àṣamọ̀

Iṣẹ́ ìwádìí lórí ṣíṣe ìfaramọlé fún àwọn ọ̀rọ̀ àyálò èdè Gẹ̀ẹ́sì onísílébù kan, pàápàá jùlọ àwọn tó ní bátáànì CVC, nínú èdè Yorùbá túbọ̀ ń tẹ̀síwájú. Ní pàtó, ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì oníhun CVC máa ń di CVVCV nínú èdè Yorùbá látàrí sísọ fáwẹ̀lì kan ṣoṣo tinú èdè Gẹ̀ẹ́sì di méjì, pẹ̀lú ṣíṣe àfibọ̀ fáwẹ̀lì ní’parí ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ (fún àpẹrẹ, cup /kᴧp/ → [kɔ́ɔ̀bù]). Àbá méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn aṣèwádìí ti gbé kalẹ̀ fún ṣíṣe ìfaramọlé fún irú àwọn ọ̀rọ̀ àyálò bẹ́ẹ̀. Ní pàtó, àwọn àbá náà dá lórí ohun tó ṣe okùnfà sísọ fáwẹ̀lì kan ṣoṣo tinú èdè Gẹ̀ẹ́sì di méjì nínú èdè Yorùbá. Àbá àkọ́kọ́ sọ pe, Yorùbá sọ fáwẹ̀lì náà di méjì láti rí i pé àtẹ̀mọ́ ìsàlẹ̀ tó máa ń wà lórí ọ̀rọ̀ oníhun CVC ti èdè Gẹ̀ẹ́sì di ohùn òkè àti ohùn ìsàlẹ̀ lórí àwọn fáwẹ̀lì méjéèjì náà nínú èdè Yorùbá. Àbá kejì sọ pé, Yorùbá fa fáwẹ̀lì náà gùn (tàbí sọ ọ́ di méjì) láti rí i pé mòráà (‘mora’) méjì tó wà nínú ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì oníhun CVC kò yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú èdè Yorùbá. Iṣẹ́ ìwádìí yìí dá sí àríyànjiyàn yìí nípa ṣíṣe àgbékalẹ̀ àbá mìíràn. Fún èmi o, àyàbá lásán ni àwọn àbá méjéèjì wọ̀nyìí jẹ́; ohun tó ṣẹlẹ̀ gan ni wípé Yorùbá sọ fáwẹ̀lì náà di méjì láti rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ àyálò èdè Gẹ̀ẹ́sì onísílébù kan wọ̀nyẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyí tí í ṣe ọ̀rọ̀-orúkọ, di ọ̀rọ̀ onísílébù méjì nínú èdè Yorùbá nítorí pé kò sí ọ̀rọ̀-orúkọ kankan nínú èdè Yorùbá, yálà aṣẹ̀dá tàbí àìṣẹ̀dá, tí sílébù rẹ̀ kéré sí méjì. Ohun tí àbá titun yìí gùn lé lórí gan ni pé, èdè tó yá ọ̀rọ̀ lò máa ń rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ faramọlé, kìí ṣe pé ó fẹ́ kí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú ìhun tàbí bátáànì tí wọ́n ní nínú èdè tí wọ́n ti ń bọ̀. Orí tíọ́rì ọptimálítì ni a gbé ìtúpalẹ̀ tí a ṣe nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí kà. Púpọ̀ nínú àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò tí ó jẹyọ nínú pépà yìí wá láti inú àwọn iṣẹ́ ìwádìí tí a ti ṣe ṣáájú, a sì gba èyí tó kù lẹnu àwọn aṣafọ̀ abínibí èdè Yorùbá tí a ṣàyàn. Ọ̀rọ̀ àyálò èdè Gẹ̀ẹ́sì méjìlélógójì ni a ṣàyàn fún ìtúpalẹ̀ tí a ṣe nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí.

Data
Created 2024-Dec-31
Changed 2025-Jan-1
Size 740.46 KB
Author This email address is being protected from spambots. You need JavaScript enabled to view it.
MD5 Checksum f274cce084b4a5841eb241a679972e88
Created by Hasiyatu Abubakari
Changed by Hasiyatu Abubakari
Downloads 23
SHA1 Checksum 4d44842d84455b4f86ca94fd275ebf5d1a902d0b
Save
Cookies user preferences
We use cookies to ensure you to get the best experience on our website. If you decline the use of cookies, this website may not function as expected.
Accept all
Decline all
Analytics
Tools used to analyze the data to measure the effectiveness of a website and to understand how it works.
Google Analytics
Accept
Decline
Unknown
Google Analytics
Accept
Decline
Google Analytics
Accept
Decline
Functional
Tools used to give you more features when navigating on the website, this can include social sharing.
PHP.net
Accept
Decline